Universal Code of Conduct/Enforcement guidelines/Voter information/yo

This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Enforcement guidelines/Voter information and the translation is 91% complete.
Outdated translations are marked like this.
Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí

Ìbò kan lati fi ọwọ́ sí àwọn Ìlànà Àmúṣẹ fún Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé yóò wáyé ní ọjọ́ keje, osù kẹta, ọdun 2022 sí ọjọ́ kókalelogun, osu kẹta, ọdun 2022 nípasẹ̀ SecurePoll. Gbogbo olùdìbò tó yẹ láàrin Àwùjọ Wikimedia yóò ni àǹfààní lati f'aramọ́ tábí tako gbígba àwọn Ìlànà Ìmúṣẹ wọlé, kí wọ́n sì sọ ìdi rẹ̀. Ìfọwọ́sí àwọn ìlàna ìmúṣẹ ṣe pàtàkì lati s'àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà àti ètò ìmúṣẹ fún Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé. Rí àlàyé síi lórí àwọn ìtọ́sọ́nà ìdìbò àti yíyẹ olùdìbò nísàlẹ̀ yìí.

The vote is closed and the results have been published. The proposal is approved.

Bakan náà, ri awọn IBEERE Ìdìbò fún ìwífún lórí didìbò kan.

Pè fún àwọn olùyọ̀nda ìpolongo Olùdìbò

Ṣé o fẹ́ ṣe ìrànwọ́ láti mú kí iye olùdìbò gbèrú síi ní àwùjọ rẹ? O kò nílò láti ní ìrírí nínú àwọn ètò ìdìbò tàbí ìtẹ̀ka. Àwọn olùyọ̀nda le báwa sọ fún àwọn àwùjọ wọn nípa ìfọwọ́sí ìbò. A kí àwọn Olùyọ̀nda láti gbogbo Iṣẹ́ Wikimedia káàbọ̀! Ṣe ìrànwọ́ láti ríi pe ohùn àwùjọ àti àwọn ìnífẹ̀ẹ́sí rẹ wà nínú ìfọwọ́sí ìbò (ọjọ́ keje sí ìkọkànlélógún, osù kẹta, ọdun 2022) nípa mímú kí àwùjọ rẹ kọpa! O le ṣe èyí nípa fífi orúkọ sílẹ̀ lórí Meta-wiki lati gba àwọn ìròyìn ìgbàdégbà, lílo ojú-ewé ọ̀rọ̀ fún àwọn ìbéèrè nípa ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀, tàbí ó le kàn sí wa ní ucocproject@wikimedia.org

Ètò Ìdìbò

Tí o bá yẹ lati dìbò:

  1. Ṣe àtúnyẹ̀wò Àwọn Ìlànà Ìmúṣẹ fún ilana-iṣeÒfin Ìhùwàsí Àgbáyé.
  2. Pinnu bóyá láti f'aramọ́ tábí tako gbígba àwọn Ìlànà Ìmúṣẹ wọlé. Bí o bá ntako àwọn ìlànà náà, kọ àwọn ìyàtọ̀ ìmọ̀ràn-ìṣe sí àwọn Ìlànà sílẹ̀ lati fikún pẹ̀lú ìbò ré.
  3. Kọ́ bí o ó ṣe ká ìbò rẹ sílẹ̀ pẹ̀lú SecurePoll.
  4. Lọ sí ojú-ewé Ìdìbò SecurePoll kí o sì tẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà.
  5. Rán àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ yòókù létí lati dìbò!

Kinni à ń dìbò lé lórí?

Àjọ Alábòójútó Wikimedia Foundation f'aramọ ìbò àwùjọ kan lori imọran àwọn Ìlànà Ìmúṣẹ Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé nipa títẹ̀lé ìfọwọ́sí ti Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé Àjọ fúnrarẹ̀. Àwọn Alábòjútó dá ìránlọ́wọ́ irú ìbò bẹ́yén mọ̀ bakan náà tí a fihàn nípa lẹtà àjùmọ̀kọ ti awọn Ìgbìmọ̀ Ìlàjà àti ìwádìí kan ti àwọn asiṣẹ́ ìyọ̀nda, ọmọ ẹgbẹ aláfàmọ́ra, àti ìgbìmọ̀ àkọsílẹ̀.

Ọkan nínú kọkọ awọn ìmọ́ràn ìṣe ti ìlẹpa ìmúṣẹ́ṣe fún ọdun 2030 jẹ́ ìdásílẹ̀ ajumọṣe ti Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé lati pese ipẹtẹlẹ agbaye to ni iwa to ṣe ìtẹ́wọ́gba fun gbogbo ajọ laisi ipamọra fún iyọlénu.

Awọn Ilana Ìmúṣẹ ti Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé

Awọn ilana yii wa fún ìmúṣẹ Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé. Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé ti jẹ́ fífi ọwọ́ sí tẹlẹ nipa awọn Ajọ Alabojuto, bi o tilẹ jẹ pe awujọ naa ko tii fọwọ sii. O pẹlu awọn iṣe idiwọ, itẹlẹmuyẹ, ati iwadii,ati awọn igbesẹ miran tí a ṣe lati yanju irufin Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé. Ìmúṣẹ yoo waye nipasẹ̀, sugbọn ko pin si, awọn amuṣẹse ti a ti yan kaakiri gbogbo iṣẹ, iṣẹlẹ Wikimedia lori ayelujara ati loju-aye, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, ati awọn ààyè to papọ to waye lori awọn gbagede ẹlomiran. Yoo waye lọna to l'eto, loju ọjọ ati ni siṣẹ-n-téle kaakiri gbogbo ajọ Wikimedia.

Awọn ilana Ìmúṣẹ Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé pin si ọna meji:

  • Iṣẹ Idiwọ
    • Ìmọ̀ igbega Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé, didamọran ikẹkọọ, laarin awọn miiran.
  • Iṣẹ Idahunsi
    • Siṣe alaye eto kan fun akọsilẹ, Siṣèto awọn irufin ti a jabọ, Pipese awọn ohun amulo fun awọn irufin ti a jabọ, Siṣẹda awọn igbesẹ ìmúṣẹ fun irufin, abbl...

Idi wo ni ó fi yẹ kí o fi dibo?

Ìfọwọ́sí awọn ilana ìmúṣẹ ṣe pataki lati kadìí awọn ọna-iṣe àmúṣẹ, awọn eto ati igbesẹ fun Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé. A ti ṣẹda Idibo lori awọn Ilana Ìmúṣẹ lati ṣe igbelewọn ifaramọ awujọ fun Òfin Ìhùwàsí Àgbáyé ati lati ṣe akojọọ̀ ijabọ bi awọn oludibo ba ni ariwisi nipa awọn igbero to wa ńlẹ̀. Ọna to ba jẹ, o ṣe pataki lati jẹ ki wọn gbọ ohun rẹ nipaṣẹ ibo rẹ, bi o ba si n dibo "bẹ́ẹ̀kọ́", o ṣe pataki ki o ṣe afiye (àwọn) ibi awọn ilana naa ti o ni awọn aniyan nipa,àti idi.

Pataki julọ, idibo yoo:

  • Rii daju pe iwoye iṣẹ Wikimedia rẹ ní asoju ni ibo agbaye.

Bi a ti n dibo

 
A mockup of the SecurePoll ballot. Note especially that votewiki may suggest you are not logged in. Your vote will still count.

Jọwọ ka abala yii ki o to lọ si SecurePoll lati kọ iranwọ iwifun lati mu ki iriri idibo rẹ lọ wọọrọwọ.

* Iwe-idibo yoo pese ibeere idibo, yoo si pese ipin meji: "Bẹẹni" ati "Bẹẹkọ"
  • Apoti "Alaye" yoo pese ibi kan fun ọ lati fi awọn alaye lori aniyan kankan ti o ba ni pẹlu awọn ilana ti a gbero.
  • Nígbà náà ni SecurePoll yoo fi to ọ leti pe ibo rẹ ti jẹ kikọsilẹ.
  • O le tun ibo di ninu eto idibo naa. Yoo pa ibo ti tẹlẹ rẹ. O le ṣe eyi laimọye igba bi o ba ṣe wu ọ.

Bawo ni abayọri idibo yoo ṣe jé siṣe?

Ipele iṣẹlẹ to ga ju idaji ifaramọ awọn olukopa ni a ó nilo lati kọja s'ọdọ ìfọwọ́sí àwọn Ajọ Alamojuto. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ajọ naa ko ni iṣe kan yika awọn eto idibo to yege tabi kuna lati tẹle (awọn eto kan nlo nkan to sunmọ ọpọ (ida meji ninu méta), nigba ti awọn yooku lo ọ̀pọ̀ lasan (idaji ati ẹyọ kan), nigba ti awọn yooku yago fun ibo onka lapapọ). Fun eto yii, lati wa ni ilana pẹlu ipinu ọpọ ninu iriri iṣeto agbaye, ibo ọpọ lo jẹ yiyan.

A o bi awọn oludibo pe awọn nkan wo lo nilo lati yatọ ati idi. Bi ibo naa ba pese ọpọ ìbò "bẹ́ẹ̀kọ́", ikọ̀ iṣẹ ofin ihuwasi yoo fi orukọ pamọ wọn yoo si ṣe atẹjade awọn idi ti oludibo "bẹ́ẹ̀kọ́" sọ, wọn yoo si pese ijabọ ni soki. Awọn ọmọ Igbimọ Akọsilẹ Ofin Ihuwasi mejeeji ni a o pe lati di Ìgbìmọ̀ Ayẹwo; ẹgbẹ yii yoo wo ṣíṣe igbelarugẹ si awọn Ilana naa latari awọn aniyan ti o jẹyọ ninu eto idibo náà. Ni ifarapẹ eto yii, awọn ayẹwo naa yoo jẹ titẹ jade fun atunyẹwo, ibo ẹlẹkeji yoo si waye.

Ṣe awọn eniyan ni ita Wikimedia Foundation yoo kopa ninu isayẹwo ibo naa lati ṣe atunyẹwo ododo?

Awọn ọmọ ẹgbẹ Wikimedia ti kii ṣe osisẹ yoo wo abajade ibo naa finnifinni fun awọn mọdaru pẹlu iriri ninu ajọ idibo ati awọn eto isamudaju. Awọn oluyẹwo ìbò finnifinni ni:

  • Sj - Alabojuto tẹlẹ ri, iriju tẹlẹ ri
  • User:Tks4Fish - Iriju lọwọlọwọ, Olusakoso Wikipedia ara Pọtigi, Oluyẹwewo ati Olusakiyesi
  • Matanya – current steward, admin on hewiki and Commons, member of the Small Wiki Monitoring Team
  • TheresNoTime – current steward, administrator, checkuser and oversighter on enwiki, admin on Meta

Amuyẹ Idibo

Awọn Ajọ Alabojuto Wikimedia ti ṣe amuyẹ fun idibo. Gbogbo olukopa Wikimedia to ti f'orukọ silẹ to kun oju osuwọn amuyẹ iṣe to kere julọ, alafamọra ati osiṣẹ Wikimedia Foundation ati olugbaṣẹse (ti a gba siṣẹ saaju ọjọ kẹtadinlogun, osu kinni, ọdun 2022), ati awọn alabojuto Wikimedia Foundation lọwọlọwọ ati tẹlẹ ri, yoo ni anfaani lati dibo lori ìmúṣẹ awọn ilana igbofinro ni SecurePoll.

Àwọn Olootu

O le dibo lati akanti rẹ kan ṣoṣo tí o ní tí o forukọ rẹ silẹ lori Wikimedia wiki. O le dibo lẹẹkan soso, lai nii se pẹlu iye akanti tí o ni. Lati yege, akanti kan yii gbọdọ:

  • jẹ eyi ti ko ni idena ni ju iṣe kan lọ;
  • Ko si gbọdọ jẹ ẹrọ;
  • o si gbọdọ ti ni o kere tan atunṣe 300 saaju ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022 kaakiri Wikimedia wikis;
  • o si gbọdọ ti ni o kere tan atunṣe 20 laarin ọjọ keje, osu kẹjọ, ọdun 2021 si ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022.

amulo AmuyẹAkanti le jẹ lilo lati tete ṣe atunyẹwo ipilẹ amuyẹ idibo olootu.

Awọn Olumudagbasoke

Awọn Olumudagbasoke yege lati dibo bi wọn:

  • ba jẹ olumudagbasoke manamana-ara Wikimedia pẹlu igbaaye
  • tabi ti ni o kere tan asopọ mọ ọkan ninu Wikimedia repos lori Gerrit, laarin ọjọ keje, osu kẹjọ, ọdun 2021 si ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022

Afikun àwọn gbedeke:

  • tabi ti ni o kere tan asopọ mọ repo kankan ninu nonwmf-extensions tabi nonwmf-skins, laarin ọjọ keje, osu kẹjọ, ọdun 2021 si ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022
  • tabi ti ni o kere tan asopọ mọ ọkan ninu ohun imulo Wikimedia repo (fun apẹẹrẹ magnustools) laarin ọjọ keje, osu kẹjọ, ọdun 2021 ati ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022.
  • tabi ti ni o kere tan atunṣe 300 saaju ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022 ki o si ti ni o kere tan atunṣe 20 laarin ọjọ keje, osu kẹjọ, ọdun 2021 si ọjọ keje, osu keji, ọdun 2022 lori translatewiki.net.
  • tabi awọn olusetọju/olukopa ninu ohun amulo, ẹrọ, olumulo akọsilẹ, irinṣẹ, ati modulu ti Lua kan lori Wikimedia wikis.
  • tabi ti kopa gidigidi ninu iṣẹda ati/tabi àwọn ètò atunyẹwo awọn eto idagbasoke imọ to so pọmọ Wikimedia

Se akiyesi: Bi o ba kun oju osuwọn gbedeke gangan, o le dibo lẹsẹkẹsẹ. Latari awọn ìdènà imọ-ẹ̀rọ ti SecurePoll, awọn eniyan to kun oju osuwọn afikun gbedeke le ma lè dibo taara, ayafi ti wọn ba kun oju osuwọn gbedeke yooku. Bi o ba ro pe o kun oju osuwọn àwọn afikun gbedeke náà, jọwọ tẹ imeeli si ucocproject@wikimedia.org pẹlu ironu o kere tan ọjọ mẹrin saaju ọjọ ti idibo yoo pari.

Awọn osiṣẹ ati alagbaṣẹse Wikimedia Foundation

Awọn osiṣẹ ati alagbaṣẹse Wikimedia Foundation lọwọlọwo yege lati dibo bi wọn ba ti n siṣẹ fun Wikimedia Foundation ni ọjọ kẹtadinlogun, osun kinni, ọdun 2022.

Awọn Osiṣẹ alafaramọ ati alagbaṣẹṣe Ajọ Wikimedia

Orí Ìwé Wikimedia lọwọlọwọ, Akori Ile-iṣẹ tabi ẹgbẹ osiṣẹ olumulo ati alagbaṣẹṣe yege lati dibo bi wọn ba jẹ osiṣẹ ile-iṣẹ wọn ni ọjọ kẹtadinlogun, osu kinni, ọdun 2022.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ Ajọ Wikimedia Foundation

Awọn ọmọ ẹgbẹ Ajọ Alabojuto Wikimedia Foundation lọwọlọwọ ati tẹlẹtẹlẹ yege lati dibo.

Awọn IBEERE Idibo

  1. Bawo ni mo ṣe le s'aridaju amuyẹ mi?
    Awọn Olootu le lo amulo AmuyẹAkanti lati s'aridaju amuyẹ ninu idibo to nlọ lọ́wọ́. Oju-ewe iwifun akanti agbaye wa ní arọwọto lati kẹkọọ sii nipa onka atunṣe àti ilọwọsi itan-akọlẹ.
  2. Bawo ni iseto osuwọn amuyẹ?
    Ajọ Wikimedia Foundation ti seto awọn osuwọn amuyẹ saaju ibẹrẹ idibo naa. Awọn wọnyi ni àmúyẹ kan naa ti a lo fun eto idibo awón Ajó Alabojuto.
  3. Oludibo to yẹ ko le dibo
    O le gba iṣẹ́-rírán kan: "A tọrọ àforíjì, o ko si ninu akojọ awọn olumulo ti a fun l'aṣẹ tẹ́lẹ̀ lati dibo ninu eto idibo yii."
    Ojutuu

    Ríi daju pe o tẹ̀ wọlé.

    Ríi daju pe o ndibo lati Metawiki, o le lo ila-isopọ yii lati lọ si oju-ewe ibẹrẹ idibo.

    Bi o ba jẹ olumudagbasoke, ọmọ ẹgbẹ osiṣẹ tàbí Ìgbìmọ̀ Olùdámọ̀ràn Wikimedia Foundation, Igbimọ Idibo le ma tii le so ọ pọ mọ ilo-orukọ pato kan. O yẹ kí o kan si ucocproject@wikimedia.org lati fi ọ sori akojọ naa.

    Bi o ko ba le dibo sibẹ ti o si gbagbọ pe o yẹ ko dibo jọwọ fi iṣẹ́-rírán kan silẹ sori oju-ewe ọrọ idibo tabi ki o kan si Igbimọ Idibo ni ucocproject@wikimedia.org. Ó yẹ kí ìdahun kan ọ lara laarin wakati mejilelaadọrin.

  4. Nko le tẹ̀ wọle si inu VoteWiki
    O ko nilo lati tẹ̀ wọle sinu VoteWiki lati dibo. Bi o ba ri iwe idibo, SecurePoll ti da ọ mọ niyẹn. Fún awọn idi aabo, awọn akanti perete lo le f'orukọ silẹ lori VoteWiki.
  5. Njẹ ẹnikẹni le ri ẹni ti mo dibo fun?
    Rara, eto idibo náà ni aabo. Eto idibo nlo sọfweà SecurePoll. Ibo jẹ ohun asiri. Ko si ẹnikan lati Igbimọ Eto Idibo, Ajọ, tabi ẹnikẹni lara awọn osiṣẹ Wikimedia Foundation to ni aaye si wọn. Ọmọ ẹgbẹ Igbẹkẹle ati Aabo ni Wikimedia Foundation lo mu kọkọrọ aabo fún eto idibo naa lọwọ. Kete ti kọkọrọ naa ba ti bẹrẹ iṣẹ, idibo yoo dawọ duro.
  6. Iru awọn datà wo la ngba nipa awọn oludibo?

    Awọn alaye ohun afojuri ara-ẹni lori awọn oludibo le ṣee ri fun awọn ẹni perete kan ti a yan to n s'ayẹwo ati s'akojọ eto idibo naa (A o kede awọn olusayẹwo ìfọwọ́sí laipẹ).

    Eyi pẹlu adirẹsi IP ati asoju olumulo. Datà yii yoo parẹ funrarẹ ni aadọrun ọjọ lẹyin idibo.

  7. Iru awọn datà wo la ngba nipa awọn oludibo?
    Awọn isẹlẹ nipa idibo yii ni a o kojọ lori oju-ewe abajade idibo lori Meta ati ijabọ itusi-wẹwẹ eto idibo naa. Ko si iwifun idanimọ ara-ẹni ti a o tẹ jade. Iwifun idanimọ ara-ẹni yii le jẹ lilo lati mọ iye awọn oludibo to daduro ati bí awọn oludibo agbaye ṣe fọnka sí.
  8. Nigba ti mo dibo, nko ri idaniloju pe ibo mi ti jẹ gbigba, ati pe iṣẹ́-rírán to han sọ wipe mo nilo lati tẹ̀ wọle lati dibo. Ki lo n sẹlẹ

    O ko nilo lati tẹ̀ wọle si votewiki lati dibo. Aṣiṣe yii ṣeeṣe ko jẹ ohun ifipamọ. A tọrọ àforíjì fún idojukọ yii; jọwọ gbiyanju lati dibo lẹẹkan sii ni m:Special:SecurePoll/vote/391. #: O yẹ ki eyi gbe iṣẹ́-rírán kan jade si ọ wipe "Ibo naa yoo jẹ didi lori aarin gbùngbùn wiki. Jọwọ tẹ bọtini isalẹ lati sun ọ sibẹ." Titẹ bọtini naa yoo sun ọ si ibi idibo o si yẹ ko gba ọ laye lati dibo.

    Bakan naa s'akiyesi pe o l'anfaani lati yan tabi paarọ ààyo idibo rẹ ni aimọye igba bo ṣe wu ọ. Ibo kan péré fun olumulo kan la o fi pamọ, ẹrọ naa yoo kan paarọ (àwọn) ibo ti tẹlẹ pẹlu tuntun, yoo si pa (awọn) ibo ti tẹlẹ yòówù rẹ.

    Nigba ti eto idibo rẹ ba pari, ẹri idibo kan yoo han loju ìwòye rẹ, eyi ti o le fi pamọ gẹgẹ bi ẹri pe o ti dibo.

  9. Bawo ni ẹrọ idibo yoo ṣe wa ni ipamọ fun awọn olumulo to ndi ọpọlọpọ ibo?
    Ibo kan pere fun olumulo kan lo npamọ lori ẹrọ naa. O ni anfaani lati yan tabi paarọ ààyò idibo rẹ ni aimọye igba bi o ṣe wu ọ. Ẹrọ naa yoo kan paarọ (àwọn) ibo ti tẹlẹ pẹlu tuntun, yoo si pa (awọn) ibo ti tẹlẹ yòówù rẹ.
  10. Njẹ ẹ nfi ipa mú tabi rọ awọn osiṣẹ lati dibo lọna kan pato?
    Rara, a ko rọ awọn osiṣẹ Wikimedia Foundation ati awọn alasomọra lati dibo lọna kan pato. A nrọ gbogbo eniyan lati dibo funra wọn. Fun awọn ìlana ìmúṣẹ Ofin Ihuwasi lati muna doko, a nilo otitọ lati ṣe iranwọ ati mọ bi awọn ibi to nilo igbesoke ba wa.
  11. Njẹ awọn ẹgbẹ Igbẹkẹle ati Aabo ṣe ojusaaju pẹlu abajade ibo náà?
    Ẹka Igbẹkẹle ati Aabo ni ipin mẹta: ilana-iṣe ofin, Iroyinkiroyin, ati Iṣesi. Ikọ̀ to nṣe kokari Ofin Ihuwasi Agbaye ni ikọ̀ Ilana-iṣe ofin. Ikọ̀ ilana-iṣe ofin ko lọwọ si awọn iṣewadii ihuwasi olumulo. Bi ko se ṣee gbagbọ pe ikọ̀ Amuṣẹṣe yoo tabi le ṣe ojusaaju, iyasọtọ amulo iṣe yìí jẹ ohun ti a mọọmọ ṣe lati yago fun ojusaaju kankan. Ikọ̀ ilana-iṣe ofin ko se yẹwo nipa boya iwe ti ajumọ sẹda de ibi ifọwọsi tabi ko de ibẹ ni igba akọṣe rẹ tabi o nilo idagbasoke sii. A seyẹwo ikọ̀ naa ẹwẹ lori boya o siṣẹ daradara pẹlu awujọ naa. Eyi tumọ si síṣe imudagba ọna ajumọṣe lati ṣe àmúṣẹ Ofin Ihuwasi Agbaye eyi ti yoo siṣẹ fun awujọ. Afojusun wa ni lati ṣe ojuṣe naa bi o ti seeṣe.
  12. Awọn ibeere miran ti a ko darukọ nibi
    Fun awọn asiṣe lile tabi ẹrọ ibo, jọwọ fi imeeli ranṣẹ si ucocproject@wikimedia.org. Jọwọ sọ orukọ-ilo ti o ngbiyanju lati fi dibo ni pato ati ibi iṣẹ ti o ti ngbiyanju lati dibo. Ọmọ ẹgbẹ iṣẹ naa yoo dahun si imeeli rẹ laipẹ jọjọ.