Leadership Development Working Group/Content/Leadership Definition (Initial Draft)/yo
This initial draft definition was published by the Leadership Development Working Group on September 15, 2022. The working group hosted a call for feedback to gather feedback about the draft. You can view the revised definition for the latest version.
Akọpamọ Definition
Ìfiléde
Ní nkan bí oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, ìgbìmọ̀ LDWG ṣe akọsílẹ̀ oríkì fún Leadership Development Working Group pẹ̀lú ìlànà ìṣeẹ́ ati àwùjọ tí wọ́n ti wa. Wọ́n dá oríkì yí sílẹ̀ pẹ̀lú ìforikorí gbogbo ìgbìmọ̀. A fi àyè sílẹ̀ fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ aláfikún sí iṣẹ́ Wikimedia lápapọ̀ fún ìgbéyẹ̀wò ati èsì lórí oríkì tí ó bá tún bá ìgbìmọ̀ náà mu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n gbé lọ́wọ́.
Oríkì gbogbo gbò fún Ipò Aṣáájú
Ipò Aṣáájú jẹ́ ohun tí ó ni ṣe pẹ̀lú ìgbésẹ̀ àti ìṣesí tí ó rọkiriká ìgbésí ayé ọmọnìyàn káàkiri àgbáyé tó fi mọ́ ẹ̀sìn, àṣà, èdè ati ọrọ̀-ajé.
A lè ri ìṣesí ipò aṣáájú nínú ìmọ̀ àti kí ọpọlọ ènìyàn ó pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìṣesí aṣá aṣáájú kò ní nkan ṣe pẹ̀lú kí ènìyàn jẹ́ adarí níbìkan kan, àmọ́ a lè rí àpẹẹrẹ ati ìṣesí aṣáájú lára bí àwọn ènìyàn ṣe ń sìṣẹ́ papọ̀, pàá pàá jùlọ bí wọ́n ṣe ṣe ìjíròrò, ìyanṣẹ́ fún ara wọn ati bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti mú èrò ọkàn wọn ṣẹ
Ipò aṣáájú ni a lè pe ní ọ̀nà tí a lè gbà láti tọ́ni, ṣí ọkàn ẹni pátá, mórí ẹni-wú, gbani níyànjú láti lé jẹ́ kí wọ́ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ fún àṣeyọrí ọjọ́ iwájú.
Ọ̀nà mẹ́ta míràn tí a tún pín ipò aṣáájú sí ni:
- Ìgbésẹ̀ rere àwọn adarí
- Ṣíṣe agbékalẹ̀ àròbájọ tó kùnà lórí ohun tí ó ṣe kókó ṣe pàtàkì fún èrò ọkàn wọn.
- Ṣíṣe itọ́ni àti ìkúnlápá fún àjọrọ̀ èrò lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà mú àfojúsùn wọn ṣe.
- Fífi àyè sílẹ̀ fún ìmọ̀ran ọlọ́pọlọ pípé láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lórí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà láti ṣe ohun ọ̀tun.
- Fífọkan tán ara-ẹni lórí àròbájọ tí wọ́n bá gbé kalẹ̀.
- Ṣíṣe ìwúrí, ìkúnlápá ati àtìlẹyìn fún gbígbé ìgbésẹ̀ tó lọ́ọ̀rìn lórí ohun tí wọ́n bá jọ gbé kalẹ̀.
- Ṣíṣe ìgbìyànjú láti dojú kọ ìpènijà èyíkéyí tí ó bá súyọ lórí ìgbésẹ̀ àti mú àfojúsùn wọn ṣẹ.
- Gbígbọ́ra ẹni yé àti ṣíṣe atìlẹyìn fún akitiyan àwọn tókù nípa fífàyè gba ìṣeẹ́ ati akitiyan olúkúlùkù wọn.
- Ohun tí a fi ń mọ aṣíwájú gidi
- Àforítì: Líláforítì lórí onírúurú ìṣòro, yóò sì tún wá ọ̀nà míràn tí ó lè gbà láti fi ṣ3 aṣeyọrí lórí ìṣoro rẹ̀.
- Ìdàgbàsóké: Aṣíwájú gidi yóò ma kẹ́kọ́ lára àwọn àṣeyọrí ati ìpèníjà rẹ̀ láti dàgbà si nínú ìmọ̀. Yóò sì lè mọ ọ̀nà ọ̀tun tí ó lè gbà láti borí ìṣòro
- Ìbọ̀wọ̀fún: Aṣíwájú gidi yóò bọ̀wọ̀ fúnra rẹ̀ nípa kí ó jẹ́ olóòótọ́, olùfọkàn tán aládéhùn.
- Àfojúsùn: Aṣíwájú yóò ní àfojúsùn fún èrò rẹ̀ gbogbo àti ọ̀nà tí yóò gbà mú àwọn èrò rẹ̀ ṣẹ.
- Akin: Aṣíwájú kò gbọ́dọ̀ ya ojo láti ṣe àṣìṣe, ó gbọ́dọ̀ lè dáàbò bo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ kẹ́kọ́ nínú àsìṣe àti àṣeyọrí àwọn ènìyàn míràn pẹ̀lú kí ó lè délẹ̀ ìlérí.
- Ìgbàmọ́ra: Aaíwájú gbọdọ̀ ní ẹ̀mí ìgbàmọ́ra, kò gbọdọ̀ ma ṣe gbogbo ẹ̀gbin ní tamínù.
- Ìjíyìn: Aṣíwájú gbọ́dọ̀ lè jíyìn fún gbogbo ìgbésẹ̀ rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ mọ bí a ti ń lo akókò tìrẹ ati ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
- Ipa jíjẹ aṣíwájú gidi
- Awọn ènìyàn yóò lè lo ẹ̀bùn ọpọlọ wọn fún rere.
- Awọn ènìyàn yóò lè mú àfojúsùn wọn ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn.
- Àwọn ènìyàn yóò pa ọkàn pọ̀ láti iṣẹ́ wọn.
- Wọn yóò lè ní ìdánilójú wípé èrò ati ìròrí àwọn kò sọnù.