Universal Code of Conduct/Drafting committee/Phase 2 meeting summaries/yo
Ojú-ewé yìí ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìsọníṣókí àwọn ìpàdé Ìgbìmọ̀ kíkọ fún ipele ìkejì Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
2021
Ìjókò àkọ́kọ́ - May 13
Àwọn ará ìgbìmọ̀ kíkọ, àwọn òṣìṣẹ́ Wikimedia Foundation, àti àwọn olùṣètò fún àkànṣe yìí jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣ'ẹ̀dá ààyè tí ó dá àbò fún ìdámọ̀ràn, ìkẹ́kọ̀ nípa àwọn ibi ànlé àti àwọn ìlànà, àti bíbẹ̀rẹ̀ sí ní ṣ'ètò pẹpẹ fún ìgbìmọ̀ yìí láti kọ àwọn ìlànà fún ìgbófìnró Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ti àjọṣèpọ̀ Wikimedia.
Ní ìjókò àkọ́kọ́ yìí, àwọn ará ìgbìmọ̀ ṣe mọ̀ mí nmọ̀ ọ́, wọ́n sì kẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ tí ati ṣe ní ipele àkọ́kọ́, àwọn ìwádìí àti ìjíròrò tí ati ṣe pẹ̀lú àwọn ará àjọṣepọ̀ ní ipele ìkejì, àti iṣẹ́ tí ó nlọ lọ́wọ́. Wọ́n sì tún ṣe àyẹ̀wò àwọn òfin àti ìrètí iṣẹ́ ti wọn lórí ìgbìmọ̀ náà.
Ìjókò ìkejì - May 18
Àwọn ará ìgbìmọ̀ kíkọ jíròrò, wọ́n sì bèèrè fún àtúnṣe sí òfin ààyè ààbò àwọn àjọṣepọ̀ ọjọ́ iwájú. Àwọn ará ìgbìmọ̀ kan mú àwọn àbá wá tí a ó gbófìnlé, àwọn ará tókù yí ò sì dìbò lórí àwọn àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan si ní ìjókò tó'nbọ̀.
Àwọn ará ìgbìmọ̀ tún jíròrò lórí àwọn onkà tí ati pín fún wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní kíkọ àwọn ìlànà ìgbófìnró fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
Kíkọ́ nípa àwọn ohun tí ó wọnú ara wọn, àti ipá wọn nínú UCoC jẹ́ àkòrí gbòógì ní ìjókò kejì yìí. Àwọn ará ìgbìmọ̀ kọ́ nípa bí àwọn ohun yìí ti nípa lórí ìwà wíwù wọn àti ìṣesí wọn sí àwọn ènìyàn míìràn. Bí àwọn ìpèníjà àti ànfààní ìdánimọ̀ akọ-abo, ìlú abínibí, ipò ayé, àti ìmọ̀ ilé-ẹ̀kọ́, ṣe wọnú ara wọn, tí wọ́n sì ní ipa lórí ìgbófìnró UCoC jẹ́ àkòrí tó gbẹ̀yìn ìjíròrò náà.
Ìjókò ìkẹ́tàa - May 27
Àwọn ará ìgbìmọ̀ kíkọ ti gbà láti ṣe àtúnṣe sí òfin ààyè ààbò àwọn àjọṣepọ̀ wọn, wọ́n sì yan ọ̀nà lórí bí a ṣe lè fa ìdarapọ̀ àwọn ará tí wọn kò sí lórí àwọn ìpe wọn. Àwọn ará tún jíròrò lórí bí a ṣe lè dẹ́kùn rírú òfin yìí àti ohun tí a lè ṣe sí àwọn tó bá rú òfin náà.
Àwọn ará ìgbìmọ̀ jíròrò lórí ojú-ìṣájú àìmọ̀ àti ipa tí ó ní lórí ètò ìpìnnu ṣíṣe, pẹ̀lú àwọn ohun-èlò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí. Wọ́n ri wípé, àwọn ojú-ìsájú àìmọ̀ lè fa àwọn ìwà ẹlẹ́yà mẹ̀yà àti ìyọlẹ́nu. Nínú ìjókò fún ètò ìpinnu ṣíṣe yìí, àwọn ará ìgbìmọ̀ kópa nínú ìrírí bíi àwọn ètò ìpinnu-ṣíṣe oríṣìriṣí ṣe lè wáyé ní kíkọ àwọn ìlànà ìgbófìnró UCoC.
Ìjókò ìkẹ́rìn - June 1
Àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ kópa nínú ìjókò àlàyé, àkọ́kọ́ fún Q&A pẹ̀lú Maggie Dennis tí ó jẹ́ igbákejì ààrẹ fún Community Resilience àti Sustainability tẹ̀lé eléyìí. Nínú ìjókò yìí, Maggie fi èrò rẹ̀ hàn lórí àwọn oríṣiríṣi igun UCoC, ó sì ṣe àlàyé tó gbòòrò lórí àwọn igun òfin ìjọba tí ó tabá ohun èlò àti ìrètí fún ìgbófìnró ìlànà yìí ní ìrísí tirẹ̀.
Ní apákèjì ìpàdé yìí, A fi ìgbìmọ̀ fún kíkọ mọ àwọn oríṣiríṣi àwòṣe tí a lè lò láti fi kọ àwọn ìlànà ìgbófìnró àti ètò ìwádìí. Àwọn ará ìgbìmọ̀ jíròrò lórí àwọn àwòṣe wọ̀nyí, wọ́n sì pèsè àwọn àtúnṣe àti àbá lórí wọn. A tún gbà wọ́n níyànjú láti pèsè àwọn ètò tí wọ́n bá lérò wípé ó yẹ fún wọn náà.
Ìjókò ìkáàrún - June 10
A fún àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ ní oríṣiríṣi àwọn iṣẹ́ tí ó wà fún ṣíṣe ní àwọn ọjọ́ tí nbọ̀. A tún fi tó wọn létí ní ìwọ̀n iṣẹ́ tí a ó gbéṣe àti àkókò tí yí ò gbà ní ìtẹ̀síwájú. Àwọn ará ìgbìmọ̀ tún jíròrò lórí àwọn ìbáṣepọ̀ láàrín àwọn ẹgbẹ́ tí a ti pín wọn sí àti pẹpẹ tí ò wúlò jùlọ fún ìbáṣepọ̀ náà.
Ní apá tó gbèyìn ìjókò yìí, àwọn ará jíròrò lórí àwọn oríṣiríṣi àwòṣe fún kíkọ ní àwọn ẹgbẹ́ ti wọn. Lẹ́yìn ìjókò yìí, wọ́n fi àwọn àbá wọn hàn fún àwọn ará ẹgbẹ́ míràn, wọ́n sì yàn àwọn àwòṣe tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ fún kíkọ ìlànà ìgbófìnró ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
Ìjókò ìkẹ́fà - June 15
Ará ìgbìmọ̀ àti òṣìṣẹ́ Wikimedia Foundation Claudia Lo ṣe àgbékalẹ̀ Ìwádìí lórí Àwọn Olùfaragba Ìyọlẹ́nu fún àwọn ará ìgbìmọ̀. Ó sọ̀ro lórí àwọn ètò ìwádìí, ìmọ̀ tí a rí mú, ìfiyèsí lórí àbò ìdánimọ̀ àwọn tí ó kópa nínú ìwádìí náà, àti àwọn ohun àmúlò inú rẹẹ̀. Ó tún ṣe ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè àti àfikún látọ̀dọ̀ àwọn ará ìgbìmọ̀ tókù.
A ké sí Civvì, tí ó jẹ́ ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ ti ipele àkọ́kọ́ láti kọ́ àwọn ìrírí rẹẹ̀ lórí ìgbìmọ̀ náà, àti láti sọ̀rọ̀ lórí bíí ètò náà ṣe lọ àti àwọn ìpèníjà iṣẹ́ wọn. Ó ṣe àfihàn bíí ìgbìmọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ ìlànà UCoC àti bíí wọn ti gbée kalẹ̀ fún àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia.
Nípasẹ̀ àwọn ìrírí tí a fihàn ní apá kíní ìpàdé yìí àti àwọn ìmọ̀ràn lórí àwọn àkòrí fún kíkọ lát'ọ̀dọ̀ àwọn olùsètò, àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ gbà láti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ ìlànà lórí àwọn àkórí tí àwọn ẹgbẹ́ wọn tíi yàn.
Ìjókò ìkéèje - June 24
Láàrín ọ̀sẹ̀, àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ ṣe àwọn iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ẹgbẹẹgbẹ́. Nínú ìpàdé, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ láti máa kà àti ṣe àfikún lórí iṣẹ́ àwọn ẹgbẹ́ míràn. Nígbàtí ìpàdé náà wásí ìparí, àwọn ará gbà láti da àwọn iṣẹ́ ẹgbẹẹgbẹ́ yìí pọ̀ sí ìwé kan láti ṣiṣẹ́ papọ̀ fún kíkọ ìlànà ìgbófìnró ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ìfihàn ìlànà iṣẹ́, àwọn ìpèníjà àti àwọn èsì, láti jẹ́ kí àwọn ará àwọn ẹgbẹ́ míràn ní ìmọ̀ abẹ́lẹ̀ lórí iṣẹ́ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan.
Ìjókò ìkẹ́jọ̀ọ - June 29
Láàrín ọ̀sẹ̀, a sọ gbọgbọ àwọn ìwé-ọ̀rọ̀ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ d'ọ̀kan, àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ sì ṣiṣẹ́ papọ̀ lórí ìwé-ọ̀rọ̀ kan yìí nípa ṣiṣe àfikún sí àwọn abala ti ẹgbẹ́ míràn.
Ní apákèjì ìpàdé yìí, a pín ìgbìmọ̀ léèkansi sí àwọn ẹgbẹẹgbẹ́ láti dámọ̀ràn lórí àwọn àfikún tí a gbà sílẹ̀ nínú ìwé-ọ̀rọ̀ ọ̀kan tí gbogbo ìgbìmọ̀ ṣiṣẹ́ lé lórí. Wọ́n gbàsílẹ̀, àwọn ìbéèrè àti àfikún tí ó ní lò èrò ìgbìmọ̀ ní ọ̀kan, fún ìjíròrò ní ìjókò tó nbọ̀.
Ìjókò ìkẹ́sàn - July 8
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpàdé yìí, àwọn ará ìgbìmọ̀ jíròrò lórí àwọn ìbéèrè lórí ìgbófìnró tí ó wá sókè nínú àwọn ìpàdé àtẹ̀yìnwá tí wọn kò sì tí yanjú nínú iṣẹ́ àṣepọ̀. Lára rẹ̀ ni ìbéèrè lórí bí a ṣelè kọ́ UCoC fún àwọn ará Wikimedia, bí aṣe lè dáàbò bo àwọn iṣẹ́-àkànṣe àti olùfarajìn ní bi tí àwọ̀n ará ìta, yálà ẹgbẹ́, ìjọba, tàbí olùgbèjà, bá ní ipá lórí bí àwọn ìgbìmọ̀ ìgbófìnró oríṣiríṣi ṣe lè jọ jùmọ̀pọ̀ àti irú data tí wọ́n lè fún ara wọn ní ìgbà tó bá yẹ. Ìgbìmọ̀ yìí tún jíròrò lórí àkòrí ìbílẹ̀ ní ìbátan pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka kárí-ayé àti àwọn àjùmọ̀ṣe tó rékọjá iṣẹ́-àkànṣe kan.
Ní apá kejì ìpàdé yìí, àwọn ará ìgbìmọ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé-ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti jàn papọ̀, ṣiṣe àtúnṣe àti àyípadà. Wọ́n gbà kí ará ìgbìmọ̀ kan ṣẹ̀dá ìwé-ọ̀rọ̀ titun láìsí àwọn àfikún, tí àwọn ará ìgbìmọ̀ lè ṣààmì sí àwọn ibi tí ìpohùnpọ̀ ti wà, àwọn èyí tó nílò ìjíròrò si, àti àwọn ibi àlàfo tí ó nílò dídí.
Ìjókò ìkẹ́wàá - July 13
Ní apá àkọ́kọ́ ìpàdé yìí, àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ ṣètò ìkópa wọn nínú àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn lórí yíyan ẹni tí yí ò ṣètò àwọn oríṣiríṣi akitiyan láti mú kí ìlànà àkọ́kọ́ wà fún àgbéyẹ̀wò àwọn ará Wikimedia.
Wọ́n lo àkókò ìpàdé tó kù láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn apá ìwé-ọ̀rọ̀ tó túnbọ̀ nílò ìjíròrò. Kókó kan pàtàkì ni bíí ètò ìgbófìnró ti yẹ kó kárí tó àti bí àwọn ará Wikimedia oríṣiríṣi ṣe lè dáhùn sí rírú òfin Àlàkalẹ̀ fún Ìhùwàsí.
Ìjókò ìkọkànlá - July 22
Àwọn ará ìgbìmọ̀ lọ sínú àwọn ọ̀rọ̀ ìlànà àkọ́kọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àwọ́n olùṣètò sàmì sí àwọn apá tí ó nílò ìjíròrò si àti àwọn apá tí ó rí bíì ìparí, wọ́n jíròrò àwọn apá tí ipá wọn ga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Àkórí ìpàdé yìí míràn tún ni àwọn ọ̀nà tó dára jù láti gba èsì lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia àti bí wọ́n ṣelè ṣètò àwọn abala fún gbígb'èsì sílẹ̀ àti ṣíṣe àkópọ̀ àwọn èsì náà àti fífi àwọn èsì yìí sínú ìlànà àkọ́kọ́.
Ìjókò ìkéjìlá - July 27
Wọ́n fi apá pàtàkì nínú ìpàdé yìí sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè ìkẹ́yìn àti àwọn ọ̀rọ̀ tó takókó.
Ìgbìmọ̀ bẹ̀rẹ̀ àtòjọ àwọn ìbéèrè pàtó tí wọ́n rò pé ó yẹ kí àwọn ará Wikimedia jíròrò lé lórí. Àwọn ará gbà láti pàdé lẹ́ẹ̀kan si láàrín ọ̀sẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ ẹgbẹ́ si láti parí ìlànà àkọ́kọ́ fún àgbéyèwò àwọn ará Wikimedia.
Ìjókò ìkẹ́tàlá - August 5
Ìgbìmọ̀ fún kíkọ lo gbogbo àkókò ìpàdé yìí láti yanjú àwọn àfikú ti tẹ́lẹ̀, ní wíwá àwọn ọ̀rọ̀ àmúyẹ míràn fún àwọn ibi tí wọ́n lérò wípé kò ní òye tó nípọn, àti ṣíṣe àfikún sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó le.
Wọ́n tún jíròrò lórí àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè fi sílẹ̀ fún àwọn ará láti dáhùn àti jíròrò lórí, àti bí wọ́n ṣe lè s'àfikún àwọn èsì àwọn ará àjọṣepọ̀ padà sí nú ìlànà àkọ́kọ́.
Ìjókò ìkẹ́rìnlá - October 18
Àwọn ará ìgbìmọ̀ fún kíkọ parapọ̀ lẹ́yìn ìsinmi, wọ́n lo apá kíní ìpàdé yìí láti fi jábọ̀ ìlànà ètò fún ìgbìmọ̀, ní pàtàkì jùlọ àwọn àsìkò. Lẹ́yìn èyí, a bèrè lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ bíí wọ́n bá ti nka àwọn abala ìwé ìròyìn lórí àwọn èsì tí njáde láti orísirísi ẹ̀ka àjọṣepọ̀.
Wọ́n lo abala ìkejì ìpàdé yìí láti ṣ'àtòjọ àti ìjúwè àwọn oríṣiríṣi apá ìlànà àkọ́kọ́ tí yí ò nílò àtúnyẹ̀wò, láti pín àwọn ẹgbẹ́ tí yí ò ṣe àtúnyẹ̀wò àti àtúnṣe, àti fún ọ̀na láti dojúkọ iṣẹ́ yìí.
Session 15 - October 28
The members went through the weekly work, the roles of the U4C, arbcoms and other global roles were discussed and different forms of possible cross project arbcom were discussed.
The role of the U4C and the relation with affcom and in the conflict resolution between affiliates as well as the relation with existing arbcoms were also discussed.
Some changes to the document were discussed and made.
Session 16 - November 2
During this session the committee discussed some of the open questions and the feedback received during the community feedback round.
The definition of “small wiki” and the vulnerabilities of those projects were discussed, the ways these projects can be helped and assisted. They ways how U4C interacts with communities and some procedures were also discussed.
In the second part of this session the committee made some changes and corrections to the language within the document.
Session 17 - November 11
During this session the members of the drafting committee discussed the appeal process, how much of the process should be moved locally. The interactions between local policies, existing and new ones the projects may create, and the UCoC were also discussed.
The committee decided that in some parts the language of the document is very technical and that for some parts of it summaries should be created.
Session 18 - November 16
In the first part of the meeting, the drafting committee members discussed the updates about initiating the ratification process and editing of the final draft.
In the second part of the meeting, the drafting committee members took cognizance of various high priority issues and reached consensus on a few of them. Members volunteered to work on refining the language for the draft.
Session 19 - November 25
In the first part of the meeting, the drafting committee members focused on resolving low priority comments in the draft guildelines. In the second part, questions about ratification were discussed as well as the idea of an abstract and how it could best be created.
Session 20 - November 30
The drafting committee members discussed the options of the ratification process and voiced their opinions. Some time was spent in deciding the final editing process of the draft.
Session 21 - December 9
In the first part of the meeting, the process for finishing the enforcement guidelines and the timeline were discussed. The committee raised the question of another timeline extension. After that, the committee members worked through low to middle and high priority comments. The committee reviewed and accepted comments, as well as made some changes to wordings to make sure that it sounds like one voice. They also identified the last urgent topics that will need to be discussed in the last meeting, and referred some lower priority issues around wording to the editor group.
Session 22 - December 14
In the first part of the meeting, an extension of the timeline until early January was announced and next steps for closing the last discussions on content were organized. After that, the committee members worked through the remaining open comments, closed as many as possible and made several decisions on the last remaining urgent topics.
Session 23 - December 23
In the first part of the meeting, Maggie Dennis joined the team to give a “Thank You” speech to the committee members. The members worked on closing open comments. In the second part of the session, the members agreed on the Building Committee, among other points that were discussed and agreed upon. They also created a document where suggestions were kept for the Building Committee to consider.
2022
Session 24 - January 6
In the final meeting of the drafting committee, the suggestions following a legal department review were discussed and integrated. The committee also resolved all remaining open questions within the document. The updated guidelines will be translated and presented to the community by the end of January 2022.