Movement Strategy/Recommendations/Summary/yo

This page is a translated version of the page Movement Strategy/Recommendations/Summary and the translation is 89% complete.
Àlàyé Adarí ní Ṣókí Nípa Ètò Ìgbésẹ̀ Àjọ

Ìtàn Ètò Ìgbésẹ̀ Àjọ náà níí ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn. Àwọn ènìyàn tó má a ń kópa nínú fífúni ní ìmọ̀, àti àwọn tó má a ń ṣàmúlò ìmọ̀, àwọn ènìyàn tó kórajọpapọ̀ láti jẹ́ ara àwùjọ àti ẹgbẹ́ oníruuru tó ń fi agbára fún Àjọ wa. Ní ọdún 2017, a bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò láti ṣẹ̀dá ọjọ́-iwájú Àjọ wa. A ṣàgbékalẹ̀ Ìlànà Ètò Ìgbésẹ̀ tí yóò yọrí sí rere fún ara wa: láti di ohun amáyédẹrùn pàtàkì jùlọ ní àwùjọ ìbáraẹniṣepọ̀ fún ìmọ̀ ọ̀fẹ́ kó tó tó ọdún 2030. Láti ríi dájú pé ẹnikẹ́ni tó gbàgbọ̀ nínú ìran wa yìí lè darapọ̀ mọ́ wa, àwa ń sa ipá wa fún ìmọ̀ tó dọ́gba ati ìmọ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́.

Láàárín àkókò ọlọ́dún méjì kan, àwọn ènìyàn jákèjádò tó jẹ́ ara Àjọ náà ṣiṣẹ́pọ̀ nípasẹ̀ ìlànà ètò ìgbésẹ̀ tó hàn kedere, tó sì fààyè sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni lára àwọn ènìyàn wa láti jíròrò lórí bí a ó ṣe mú ìdàgbàsókè bá àwọn àgbékalẹ̀ wa láti lè jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nínú Ìlànà Ètò Ìgbésẹ̀ wa. Ìwé àkọsílẹ̀ yìí dúró fún àwọn àbájáde ìgbìyànjú àjọṣepọ̀ yìí: awọn ìmọ̀ràn mẹ́wàá (10) pẹ̀lú àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ìrònù tó rọ̀ mọ́ wọn, tó ṣàlàyé ìtọ́sọ́nà fún àyípadà ní ṣókí. Àwọn èròǹgbà mìíràn lo àwọn àṣeyọrí tó ti wà tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú àwọn mímọ̀ọ́ṣe àti ìrírí àgbàyanu tó jẹ́ ara Àjọ wa, tó sì rékọjá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìpílẹ̀ tí a kọ́ ohun gbogbo lé lórí. Àwọn mìíràn ń bèèrè fún àyípadà nípa bí a ti ń ṣiṣẹ́, bí a tí ń bá ara wa ṣe pọ̀, wọ́n sì ń tọ́ka sí àwọn ohun àmúṣe tí a ti fọkànsí láti ìbẹ̀rẹ̀ àti àwọn ohun tí a gbàgbọ́ pé wọ́n jẹ́ pàtàkì. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mìíràn ń bèèrè pé kí á ronú nípa àwọn ọ̀nà tuntun tí a lè má a gbà ṣiṣẹ́, tí a lè fi má a fọwọ́sowọ́pọ̀, tí a sì lè fi má a darí ohun gbogbo fún àṣeyọrí Àjọ wa.

A gbé ẹgbẹ́ oníṣẹ́ yìí kalẹ̀ nípasẹ̀ àwọn Wikimedians tó fẹ́rẹ̀ tó ọgọ́ọ̀rùn (100) jákèjádò àgbáyé, pẹ̀lú àwọn olùyọ̀ọ̀da, òṣìṣẹ́ àti àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ àjọ olùdarí àwọn ilé-iṣẹ́ tó jẹ́ aláàbáṣepọ̀ wa, àti Wikimedia Foundation, àti àwọn aṣojú láti àwọn àjọ tó ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa. Àwọn pín ara wọn sí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mẹ́sàn-án tó ní àkọlé iṣẹ́ àmúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń ṣe ìwádìí, wọ́n ń jíròrò, wọ́n sì ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èròǹgbà wọn sórí ayélujára àti lásìkò àwọn ìpàdé ìfojúkojú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ṣàjọpín àwọn èsì tó ṣàlàyé èrò wọn, wọ́n mú kí ìjíròrò náà ní àfikún àwọn ohun tó lè ran ni lọ́wọ́ síwájú síi, wọ́n sì dásí ọ̀rọ̀ náà látọ̀nàjíjìn àti níbi àwọn oríṣiríṣi àpéjọpọ̀. Àwọn ìmọ̀ràn tó wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí jẹ́ àbájáde àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pàtàkì mẹ́rin tó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù Kẹjọ (August) ọdún 2019. Nípasẹ̀ àwọn èsì tó ṣàlàyé èrò àwọn ènìyàn àti nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà wá ṣàgbéjáde ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ní oṣù Kẹsàn-án (September), tó mú àpapọ̀ gbogbo àwọn ìmọ̀ràn náà jẹ́ mọ́kàndínláàdọ́ọ̀rún (89). Àwọn wọ̀nyí ni awọn olùkọ̀wé kọ̀ọ̀kan sọ di odidi tó ní ìpín akójọpọ̀ mẹ́tàlá (13) nínú. Àwọn èsì tó jọjú tó ṣàlàyé èrò àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a gbà láti oṣù Kìíní (January) sí oṣù Kẹta (March) ọdún 2020 ràn wá lọ́wọ́ láti yọ àwọn èpò tó wà nínú àwọn ìmọ̀ràn náà kúrò ati láti ṣiṣẹ́ àṣeparí lórí wọn láti mú wọn wá sí ipò tí wọ́n wà ní báyìí: àwọn ìmọ̀ràn mẹ́wàá àti ìlànà mẹ́wàá.

Principles

Àwọn ìlànà náà jẹ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí a gbàgbọ́ pé wọ́n jẹ́ pàtàkì jùlọ jákèjádò Àjọ wa, lórí èyítí a kọ́ àwọn ìmọ̀ràn náà lé lórí, àti lórí èyítí a ó ti gbé wọn ṣe. Àwọn ìlànà náà ni: rírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ; ààbò àti ìdáàbòbò; ìpinnu-ṣíṣe lọ́ná tó fààyèsílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kópa; ṣíṣe ohun gbogbo dọ́gba láìsí ojúṣàaájú àti ìfúnnilágbára; pípín agbára àti òmìnira fún àwọn tó wà lábẹ́ aláṣẹ àgbà kan àti ṣíṣàkóso ara ẹni fúnraraẹni; ìtúpalẹ̀ èròǹgbà tó wà lẹ́yìn ọ̀rọ̀; ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àjọṣepọ̀; mímú ohun gbogbo hàn kedere àti ṣíṣàlàyé ohun gbogbo; ṣíṣe iṣẹ́ lọ́nà tí yóò mú àǹfàní ńlá jáde; àti ìfarada ohun gbogbo. Àwọn ìlànà tó so pọ̀ mọ́ ara wọn wọ̀nyí ń sọ nípa àwọn ìgbésẹ̀ tí Àjọ wa gbé láti di ohun amáyédẹrùn pàtàkì jùlọ ní àwùjọ ìbáraẹniṣepọ̀ fún ìmọ̀ ọ̀fẹ́.

Recommendations

Pẹ̀lú àwọn ìlànà náà lóókan àyà wọn, àwọn ìmọ̀ràn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá (10) ti Ètò Ìgbésẹ̀ Àjọ náà ṣàfihàn àwọn àyípadà tó gbáralé ara wọn tó la ọ̀nà fún ọjọ́-ọ̀la Àjọ Wikimedia:

  • Mú Ìlọsíwàjù bá Ìdúróṣinṣin Ipò Àjọ Wa ń pè wa láti rí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ àti láti fi ara wa fún bíbá àìní àwọn ènìyàn pàdé. Ìdúróṣinṣin Ipò Àjọ Wa dá lórí dídámọ̀ àti ṣíṣàtìlẹ́yìn fún àwọn oníruuru abánidásọ́rọ̀ wa - àwọn olùyọ̀ọ̀da tó ti fẹsẹ̀múlẹ̀ àti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé – àti àwọn ohun àmúṣe wa gbogbo. Ìmọ̀ràn yìí ṣe ìwádìí àwọn ọ̀nà tí a lè lò láti fi pín owó tí a pèsè láìsí ojúṣàájú àti àwọn àǹfàní tuntun fún ṣíṣàmúwá owó tí yóò má a wọlé, mímú gbígbajúmọ̀ Àjọ náà pọ̀ síi, mímú agbára àti ṣàmúwá owó ní agbègbè gbòòrò síi, àti mímú ìtẹ̀síwájú bá oníruuru àjọṣepọ̀.

  • Mú Ìrírí Aṣàmúlò Dára Síi ń rísí ṣíṣeélò àti ríráàyèsí àwọn àgbéjáde wa àti àwọn ọ̀nà tó ń tẹ̀síwájú tí à ń gbà mú wọn dára síi. Ó dámọ̀ràn pé kí a fún àwùjọ àwọn abánidásọ́rọ̀ àti olùmúgbèrú láàyè nínú ìwádìí, ìṣàgbékalẹ̀, àti ìdánwò àwọn oníruuru àkọsílẹ̀ àlàyé ara ẹni àti àwọn ohun èlò. Nínú wọn tún ni àwọn ohun èlò fùn àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé wà, àwọn ìlànà ìgbéléwọ̀n àkọsílẹ̀, àwọn irin-iṣẹ́ fún oníruuru iṣẹ́-àgbéṣe àti èdè, mímú ìtẹ̀síwájú bá àwọn iṣẹ́-àgbéṣe tuntun, àti ìdàgbàsókè API.

  • Ṣíṣẹ̀dá Àfẹnukò Ìhùwàsí, jíjábọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ láìdárúkọ̀, àti rírísí ìyọnilẹ́nu lẹ́nu àwọn iṣẹ́-àgbéṣe wa ní a jíròrò lé lórí nínú Ṣe Ìpèsè fún Ààbò àti Ìfààyèsílẹ̀ fún Kíkópa Gbogbo Ènìyàn. Ìmọ̀ràn yìí ń dábàá ìpìlẹ̀ fún ìhùwàsí tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà láàárín Àjọ náà, ètò ìṣàyẹ̀wò àti àmúṣe ààbò pẹ̀lú àwọn ohun amáyédẹrùn fún ìfèsì ní kíákíá, mímú ìdàgbàsókè bá agbára agbègbè fún ààbò àti ìdáàbòbò, ṣíṣe àgbàwí fún àgbékalẹ̀ òfin tó dára fún títànkáàkiri ìmọ̀ ọ̀fẹ́, àti àwọn irin-iṣẹ́ ìpamọ́ fún agbègbè láti lè ní ìdánilójú ààbò fún àwọn abánidásọ́rọ̀ wa.

  • Mú Ìdánilójú Àìṣojúṣàájú wà nípa Ìpinnu-Ṣíṣe jẹ́ pàtàkì fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣíṣàjọpín ojúṣe àti ṣíṣàlàyé ohun gbogbo láàárín Àjọ náà. Dídọ́gba ìṣojú-ẹni nìnù ìpinnu-ṣíṣe pẹ̀lú ọ̀nà tó hàn kedere, tó sí ṣí sílẹ̀, fífún àwọn àwùjọ ènìyàn agbègbè lágbára, pẹ́lú ṣíṣàjọpín àwọn ìpèsè owó àti àwọn dúkìá àjùmọ̀ni mìíràn nípasẹ̀ kíkópa gbogbo ènìyàn tó kàn, jẹ́ àwọn àkọlé tó ṣe kókó nínú ìmọ̀ràn yìí. Ó dámọ̀ràn Ìgbaniláàyè ìjọba lábẹ́ òfin fún Àjọ náà, ìdásílẹ̀ Àjọ Káríayé, àwọn ibi ìmúṣẹ́ṣe tó dá lórí agbègbè àti àkọlé iṣẹ́-àmúṣe, àti àwọn ojúṣe wọn tí a ṣàlàyé ní yèkèyèkè, àti àwọn àgbékalẹ̀ fún kíkópa gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ sí ọ̀ràn náà.

  • Títẹ̀síwájú láti ṣàfikún tó yẹ sí àwọn ipa-kíkó àti ojúṣe tí a ṣàlàyé ní yèkèyèkè, Ṣàkóso Jákèjádò Àwọn tó lọ́wọ́ sí Ọ̀ràn náà ó dámọ̀ràn ṣíṣẹ̀dá ààyè fún ìbaraẹnisọ̀rọ̀ àti àjọṣepọ̀ tó dára síi láàárín Àjọ náà àti pẹ̀lú àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀, àwọn abánidásọ́rọ̀ tó jẹ mọ́ mímọ̀ọ́ṣe wọn, àti àwùjọ àwọn olùmúgbèrú fún ìṣàkóso ìmọ̀-ẹ̀rọ. Ó dámọ̀ràn ìṣàkóso àwọn ohun èlò àjùmọ̀ni, ìdásílẹ̀ Àjọ Ìmọ̀-ẹ̀rọ fún àwọn iṣẹ́ tuntun, pàṣípààrọ̀ àlàyé tó múnádóko, àgbékiri ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tí a mú dára síi, àti àwọn àǹfàní fún ìbánikẹ́gbẹ́ fún iṣẹ́.

  • Lo ohun-ìní sínú Ìdàgbàsókè Ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti Jíjẹ́ Adarí ń wo mímú íkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ènìyàn àti mímọ̀ọ́lò ìmọ̀-ẹ̀rọ gbèrú síi láìsí ojúṣàájú, láàárín ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn àjọ tó wà lábẹ̀ Àjọ wa. Èyí nílò ìlànà ìdojúkọ létòlétò káàkiri àgbáyé pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ ní agbègbè fún àwọn oníruuru ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Àwọn ìlànà ìdojúkọ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí to yẹ, wọ́n sì lè jẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ayélujára, ìbánikẹ́gbẹ́ ìsọ̀wọ́-sí-ìsọ̀wọ́, ṣíṣẹ̀dá àkóónú lóríṣiríṣi èdè, ìtọ́nisọ́nà nípasẹ̀ ìrírí, àti ìwúrí fún ìdàgbàsókè ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Ìmọ̀ràn yìí ń dábàá ètò ìdàgbàsókè jíjẹ́ adarí tí a gbèrò bó ṣe yẹ, fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú àwọn ohun amáyédẹrùn tó rọ̀ mọ́ ọ (lórí àti láìsí lórí ayélujára) láti lè ran gbígbékirí ìmọ̀ lọ́wọ́.

  • Ṣàkóso Ìmọ̀ Inú dámọ̀ràn ríríi dájú pé ìmọ̀ láàárín Àjọ náà jẹ́ èyí tó ṣeé gbà lọ́nà tó rọrùn, tó fààyè gba kíkópa, tó sì jẹ́ èyí tí òṣùwọ̀n dídára rẹ̀ ga púpọ̀. Nípasẹ̀ ìmọ̀ràn náà, a nílò àṣà kíkọ nǹkan sílẹ̀, ibi ìpamọ́ ìmọ̀ pẹ̀lú ìráàyèsí àwọn ohun èlò ìrànlọ́wọ́ fún ẹ̀kọ́-kíkọ́, àti àtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí a yàsọ́tọ̀ fún iṣẹ́ yìí.

  • Bíbọ̀wọ̀ fún òmìnira àwọn olùyọ̀ọ̀da, Ṣe Ìdámọ̀ Àwọn Àkọlé fún Níní Ipa ń bèèrè pé kí a ní òye bí àkóónú wa ṣe ń ní ipa lórí àwọn ènìyàn, ó sì fúnni ní àwọn ọ̀nà tí a lè gbà láti rísí àwọn àayè tó wà láàárín àkóónú, láti ní òye ípalára ńlá tí àlàyé àìtọ́ ń fà sórí àwọn iṣẹ́-àgbéṣe wa, ṣe àgbàwí fún àwọn ohun èlò àjùmọ̀ni tó níí ṣe pẹ̀lú ṣíṣẹ̀dá àkóónú, kí a sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aláàbáṣiṣẹ́pọ̀ pàtàkì.

  • IMú Ohun Tuntun Jáde nínú Ìmọ̀ Ọ̀fẹ̀ bèèrè pé kí a ṣe ìwádìí, kí a sì mú àwọn oríṣiríṣi iṣẹ́-àgbéṣe wa ìlànà àkóónú wa gbòòrò síi láti lè má a jẹ́ pàtàkì ní gbogbo ìgbà àti làti lè pèsè ìráàyèsí àpapọ̀ ìmọ̀ ènìyàn. Ìmọ̀ràn yìí ń dábàá dídámọ̀, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn àwùjọ, àwọn ìlànà àti ìṣesí tó jẹ́ ìdènà sí ìmọ̀ láìsí ojúṣàájú, ṣíṣẹ̀dá ọ̀nà sí àwọn iṣẹ́-àgbéṣe tuntun, àti ṣíṣe àwọn irin-iṣẹ́ àti níní àjọṣepọ̀ láti mú kí ó ṣeé ṣe láti ráàyè sí ìmọ̀ ọ̀fẹ́ ní àwọn ìlànà oríṣiríṣi àti ní ipò tó ṣeé lò.

  • Láti lè ṣàmúlò ètò ìgbésẹ̀ tó wáyé nípasẹ̀, tó sì jẹ́ ti Àjọ náà lọ́nà tí yóò ṣàǹfàní, a nílò láti mú mímọ̀-nípa-araẹni láàárín ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn àjọ gbèrú síi, kí a sì Ṣàyẹ̀wò, Fọ̀rọ̀wérọ̀, àti Ṣàyípadà iṣẹ́ wa. Èyí nílò àwọn ohun èlò tó yẹ, mímọ̀ọ́ṣe àti agbára, ṣíṣàjọpín ojúṣe, àti ṣíṣàlàyé ohun gbogbo láti lè ṣàyẹ̀wò, láti sọ nípa ìlọsíwájú, láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́, àti láti ṣàyípadà sí iṣẹ́ wa bí ó ti yẹ.

Ṣíṣe àwọn ohun tí ìmọ̀ràn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà àti àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ìrònù tó rọ̀ mọ́ ọ sọ yóò mú kí àwọn àyípadà ìpìlẹ̀ sí àṣà àti àgbékalẹ̀ wáyé, èyí tí yóò fún Àjọ wa ní àǹfàní láti gba gbogbo àwọn tó gbàgbọ́ nínú ìran wa fún ‘ilé-ayé nínú èyítí gbogbo ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan lè pím lára àpapọ̀ gbogbo ìmọ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ ‘ wọlé. Bí a ti ń fọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú àwọn àyípadà wọ̀nyí wá sí ìmúṣẹ nínú àwọn ọdún tó ń bọ̀ lọ́nà, àwa yóò lè dojúkọ àìní gbogbo àwọn ènìyàn tó ń fún Àjọ wa lágbára àti àwọn tí àwa ń ṣiṣẹ́ fún – nísìnyí àti lọ́jọ́ iwájú – kí a sì di ohun amáyédẹrùn pàtàkì jùlọ ní àwùjọ ìbáraẹniṣepọ̀ fún ìmọ̀ ọ̀fẹ́.