Leadership Development Working Group/Call for feedback on the draft shared leadership definition/yo

Outdated translations are marked like this.

TL;DR: akọsílẹ̀ ìtumọ̀ adarí tí àjọ tí ó ń ṣíṣe lórí ìdàgbàsókè adarí gbé kalẹ̀ tí wọ́n sì ń retí àríwísí gbogbo àwùjọ lórí rẹ̀.

Jọ̀wọ́ fi èrò rẹ hàn lórí oríkì tí a gbé kalẹ̀ yí lórí ojú-ewé Meta-Wiki wa, fọ́ọ́mù èrò, tàbí kí o lo Movement Strategy láti sọ èrò rẹ. Bá kan náà ni o lè fi e-mail ránṣẹ́ sí wa ní leadershipworkinggroup(_AT_)wikimedia.org. A ń retí èsì èrò rẹ títí di ọjọ́ kọkàndínlógúnọ́gbọ̀n oṣù kẹsàán ọdún 2022.

Ẹ nlẹ́ o gbogbo ènìyàn!

Mo lérò wípé ẹ mọ̀ wípé àjọ tí ó ń ṣíṣe lórí ìdàgbàsókè adarí (LDWG) ti ń sapá láti kọ́ àwọn ènìyàn nípa bí wọ́n ṣe lè jẹ́ adarí/aṣíwájú gidi nínú àwọn wa ní nkan bí oṣù mélòó kan sẹ̀yìn? Ìgbìmọ̀ LDWG ni wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ oníṣẹ́-ọ̀fẹ́ tí wọ́n ń ṣojú àwùjọ oríṣiríṣi tí wọ́n ti wá. Inú wa dùn láti fi tó yín létí wípé a ń retí èsì tàbí èrò ẹnikẹ́ni lórí oríkì tí a gbé kalẹ̀ fún jíjẹ aṣíwájú gidi. Oríkì yí ni a gbé kalẹ̀ lẹ́yìn ìjíròrò ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ àfikúnlukùn lórí ohun tí a lè pe Leadership ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ati àfojúsùn àwùjọ WMF.

Gbìyànjú láti ka ìtumọ̀ adarí tí a kọ ránpẹ́ sílẹ̀ náà kí o sì fi èrò tàbí inọ̀sílára tìrẹ ránṣẹ́, o pẹ́ jù, kí o ti fi ránṣẹ́ ní ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹwàá ọdún 2022. Ìtumọ̀ adarí tí a kọ sílẹ̀ ránpẹ́ yí ní ìtumọ̀ adarí tí gbogbo ènìyàn mọ, àti àwọn àkóónú tí ó ṣàlàyé síwájú si nipa, ìgbésẹ̀, ìhùwàsí, ìṣe tí ó tọ̀nọ̀, àti àbáyọrí adarí tí ó dára.

Orísiríṣi ọ̀nà ni o lè gbà láti fi èrò ati èsì rẹ ránṣẹ́ sí wa. O lè lo ojú-ewé Meta-Wiki wa, fọ́ọ́mù èrò, tàbí kí o lo ojúkò Movement Strategy láti sọ èrò rẹ. Bá kan náà ni o lè fi e-mail ránṣẹ́ sí wa ní leadershipworkinggroup(_AT_)wikimedia.org.

O lè ṣe àgbéyẹwò ìtumọ̀ ránpẹ́ náà bóyá ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwọ lérò wípé jíjẹ aṣíwájú jẹ́ nínú àwùjọ wa. O sì lè tún wòó bóyá a kò fi ohun àmúyẹ kan tí ó níṣe pẹ̀lú àṣà, èdè tàbí òmíràn kun. Gbìyànjú kí o fi sọwọ́ sí wa.

Jẹ́ kí á jùmọ̀ ṣayẹyẹ ìṣọkan òun jíjẹ aṣíwájú tí kò lẹ́gbẹ́ nínú àwùjọ wa!

O ṣeun!