Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Ìwé Ìròyìn
The Universal Code of Conduct Newsletter has transitioned into the Movement Strategy and Governance Newsletter. Please go to the landing page of the MSG Newsletter to see the latest issues. |
A kí yin káàbọ̀ sí abala ìkẹ́rìn Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí, yí ó tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà. A pè yín láti fún wa ní àwọn èsì tàbí àbá lórí àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí tó nbọ̀ ní ojú-ewé ọ̀rọ̀ ìròyìn UCoC. E tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti ma túnmọ̀ àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí sí èdè ìbílẹ̀ yín, àti pínpín ìwé-ìròyìn yìí ni àwọn ojú-ewé àti pẹpẹ ìjíròrò fún àwọn ará yín.
Jọ̀wọ́ rántí láti fi orúkọ sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala ìwé-ìròyìn tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí yin, ẹ tún fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí á ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa ní ọjọ́ iwájú.
Adúpẹ́ fún kíkà àti ìdásí yin.
Ìkánlẹ̀ Àgbéyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ inú Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́
Àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yí ò wá sí òpin ní 17 October 2021, lẹ́yìn ìkànsí oṣù méjì. Àwọn olùṣètò tí ó ju méjìlá lọ lát'orí Ẹgbẹ́ Strategy Àjọṣepọ̀ àti Governance ló ti kànsí àwọn ará àjọṣepọ̀ ní èdè tóju ogún lọ, wọ́n sì ti ṣ'ètò àwọn ìjíròrò pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn olùfọwọ́sí àjọṣepọ̀ láti rí dájú wípé ètò yìí sí sílẹ̀ sí gbogbo ènìyàn.
Ní àwọn ọjọ́ ìgbẹ̀yìn àgbéyẹ̀wò àti ìkànsí yìí, àwọn olùṣètò yí ò ṣ'ètò àwọn wákàtí ìjíròrò fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka àti àwọn ìkànsí pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àti alágbàṣe Wikimedia Foundation. Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yí ò tabá gbogbo ẹni tó nṣiṣẹ́ tàbí farajìn nínú àjọṣepọ̀ Wikimedia, nítorínà, ó ṣe pàtàkì láti gba àwọn èsì sílẹ̀ látorí ọ̀pọ̀ pẹpẹ tí a bá lè rí.
Tí a bá ti kálẹ̀ àwọn ìkànsí ní 17 October 2021, Ìgbìmọ̀ Kíkọ yí ò ní ànfààní láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn èsì tí àwọn olùṣètò ti gbàsílẹ̀. Wọn yí ò ṣe àwọn àtúnṣe àti ìmúdára tí yíò dálórí àwọn èsì wọ̀nyí, kí wọ́n tó kọ ìlànà ìparí tí wọn yí ò gbe síwájú fún ìfọwọ́sí.
Àwọn Wákàtí àti Ìpè Ìjíròrò
Ní 18 September 2021, ẹgbẹ́ olùṣètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí ṣ'ètò ìjókò ìjíròrò láti sọ̀rọ̀ lórí Àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́ (EDGR) ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí. Ìjókò méjì ni ó wáyé, ọ̀kan ní 03:00 UTC àti ìkejì ní 15:00 UTC.
Olùkópa 25 ni ó wásí ìjókò ìjíròrò wọ̀nyí. Ní àsìkò yìí, láti mú ìbéèrè ìgbìmọ̀ kíkọ ṣẹ, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè gbangba lát'ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Kíkọ, pẹ̀lú ètò ìfọwọ́sí. E lè ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjábọ̀ náà lórí meta.
Njẹ́ o túnbọ̀ ní ìbéèrè tàbí àfikún fún wa? Darapọ̀ mọ́ wákàtí ìjíròrò kan tó gbẹ̀yìn ní 15 October ní 03:00 UTC àti 14:00 UTC.
Ètò ìdìbò fún Ìgbìmọ̀ kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀
Ètò ìdìbò Ìgbìmọ̀ Kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ yí ò bẹ̀rẹ̀ ní 12 October, yí ò sì wáyé fún ọ̀sẹ̀ méjì títí dé 25 October 2021. Àwọn oníṣẹ́ iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia lè dìbò fún àwọn olùdíje tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ láti yan ènìyàn méje ṣ'órí ìgbìmọ̀ náà. Àwọn ẹ̀ka Wikimediia yí ò yan àwọn ènìyàn mẹ́fà. Wikimedia Foundation yí ò yan ènìyàn méjì láti kó àwọn ènìyàn 15 pọ̀ fún ètò kíkọ Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ ní àwọn oṣù tó nbọ̀. O lè kà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ètò yì lórí meta.
Láti ṣe ìpinnu tó jinlẹ̀, à n pe gbogbo ènìyàn láti wo gbólóhùn àwọn olùdíje, níbi tí àwọn ènìyàn ti sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìrírí wọn, àti àwọn ìdí tí wọ́n fi fẹ́ darapọ̀ mọ́n Ìgbìmọ̀ Kíkọ. A sì tún ṣ'ètò "atọ́ka ìdìbò" tí yí ò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yí kiri àwọn olúdìje 70, tí a ó tẹ̀jáde pẹ̀lu ìkéde ìdìbò.
Tí o bá ní ìbéèré kankan, má ṣe dẹ́kun láti kànsí strategy2030wikimedia.org tàbí wá sí wákàtí iṣẹ́ tí yí ò wáyé ní Ọjọ́bọ̀, 12 October ní 19:00 UTC.
Ìdarí Titun fún Ìwé-Ìròyìn yìí
Bí a ṣé nkágbá ètò ìkànsí fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí, ẹgbẹ́ olùṣètò ngbèrò ìdarí titun fún ìwé-ìròyìn yìí. Fún ìdí èyí, abala Ìwé-ìròyìn UCoC yìí ni yí ò jẹ́ èyí tí ó gbẹ̀yìn fún ọdún 2021.
A ó tún ké sí yin ní ọdún tó nbọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn fún ètò UCoC, pẹ̀lúpẹ̀lú ìwé-ìròyìn yìí. Ní àsìkò ìdúró yìí, o lè ké sí wa nípa kíkọ ìwé sí wa ní: ucocprojectwikimedia.org. Jọ̀wọ́ tún tẹ̀le ojú-ewé iṣẹ́ yìí, láti ní àwọn ìmọ̀ tó pé dójú-ìwọ̀n nípa ètò yìí.
Búlọ́ọ̀gì Diff
Èyí ni àwọn àtẹ̀jádè titun lórí ètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí nínú Búlọ́ọ̀gì Diff ti Wikimedia, tí ó lè wù ọ́ láti kà. Jọ̀wọ́ yẹ̀ wọ́n wò: