Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Ìwé Ìròyìn/1/Ìfiránṣẹ́ àgbáyé

This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Newsletter/1/Global message and the translation is 100% complete.
Other languages:
Bahasa Indonesia • ‎Deutsch • ‎English • ‎Yorùbá • ‎català • ‎español • ‎français • ‎italiano • ‎polski • ‎português do Brasil • ‎русский • ‎العربية • ‎नेपाली • ‎मैथिली • ‎हिन्दी • ‎বাংলা • ‎日本語 • ‎한국어

Universal Code of Conduct News – Issue 1

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí
Abala àkọ́kọ́, Oṣù kẹ́fà 2021Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn


A kí yin káàbọ̀ sí abala àkọ́kọ́ Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí àti bí wọ́n ṣe lè túnbọ̀ kọ́pa nínú ètò náà. A ó tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà.

Ẹ jọ̀wọ́ kí è si wípé, èyí ni abala àkọ́kọ́ ìwé-ìròyìn UCoC, tí a fi ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn olùfọrúkọ sílẹ̀ àti gbogbo abẹ́-igi iṣẹ́-àkànṣe, gẹ́gẹ́ bí ìkéde fún ètò ìròyìn yìí. Tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí ojú-ewé ọ̀rọ̀ yin, abẹ́ igi iṣẹ́-àkànṣe yín, tàbí ojú-ewé ké'wé tó tọ̀nà, ẹ fi orúkọ yín tàbí ti ojú-ewé náà kalẹ̀ sí bí.

E lè ràn wá lọ́wọ́ láti ma túnmọ̀ àwọn abala ìwé-ìròyìn yìí sí èdè ìbílẹ̀ yín, kí a lè pólóngó ìròyìn nípa ìlànà yìí, kí a sì pèsè àbò fún gbogbo wa nínú àjọṣepọ̀ tí gbogbo wa fẹ́ràn yìí. Ẹ jọ̀wọ́ fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa, kí a tó tẹ̀ wọ́n jádèe. Ìkópa yín ṣe pàtàkì fún wa.

  • Àwọn ìkànsí àti ìjíròrò àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia – A fi ìpè ránṣẹ́ sí àwọn ilé-iṣẹ́ Wikimedia ní oríṣiríṣi ìwọ̀n àti irú àti ìrírí láti kọ́pa nínú àwọn ìjíròrò ati ìkànsí UCoC ní oṣù kẹ́ta títí dé oṣù kẹrìn 2021. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àwọn ìkànsí àti ìjíròrò gbòógì 2021 – Wikimedia Foundation ṣ'ètò ìjíròrò àwọn ìbéèrè ìgbófìnró ní oṣù kẹ́rìn àti oṣù káàrún 2021, láti gba èsì kalẹ̀ lórí ìgbófìnró UCoC lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àwọn ìpàdé ìjíròrò – Àwọn olùṣètò UCoC ṣ'ètò ìpàdé ìjíròrò gbangba méjì tí ó wáyé fún ìṣẹ́jú àádọ̀rún ní oṣù káàrún 2021 láti jíròrò lórí àwọn ìbéèrè gbóògì ìgbófìnró fún UCoC. Àwọn ìpàdé míìràn sì tún nbọ̀ lọ́nà. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìgbìmọ̀ fún kíkọ ipele ìkejì – Ìgbìmọ̀ fún kíkọ ipele ìkejì ti UCoC bẹ̀ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kejìlá oṣù káàrún 2021. Kà síbẹ̀ si lórí iṣẹ́ wọn.(ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Búlọ́ọ̀gì Diff – Àwọn olùṣètò UCoC kọ oríṣiríṣi búlọ́ọ̀gì lórí àwọn àkíyèsí àti èsì tí wọ́n rí gbà lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ ìbílẹ̀ tí wọ́n kàn sí ní ìbẹ̀rẹ̀ odún 2021. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)