Wikimedia Foundation elections/2021/2021-06-09/Call for Candidates/Short/yo

This page is a translated version of the page Wikimedia Foundation elections/2021/2021-06-09/Call for Candidates/Short and the translation is 100% complete.
Other languages:
Deutsch • ‎English • ‎Hausa • ‎Igbo • ‎Kiswahili • ‎Yorùbá • ‎català • ‎français • ‎isiXhosa • ‎čeština • ‎русский • ‎українська • ‎العربية
Wikimedia-logo black.svg
2021 Board Elections
Main Page
Call for Candidates
Candidates
Results
Discussions
FAQ
Questions
Organization
Documentation
This box: view · talk · edit

Ìdìbò Wikimedia Foundation sí ipò ìgbìmọ̀ olùfọkàntán ti ọdún 2021 ń bọ̀ láìpẹ́. Àwọn àyè tí ó ṣófo ni a ń retí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Wikimedia jákè-jádò agbáyé tí ó bá ní ohun àmúyẹ ó díje sí.

Ìgbìmọ̀ Olùfọkàntán ni ó ma ń ṣe amójútó gbogbo ìṣeẹ́ àkànṣe Wikimedia pátá pátá. Àwọn tí àjọ Wikimedia nígbàgbọ́ sí àti àwọn olùfọkàn tán ni wọ́n ń lara jọ di ìgbìmọ̀ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ni inú ìgbìmọ̀ yí ni wọn yóò lo ọdún mẹ́ta. Gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Wikimedia lágbàáyé ni wọ́n ní ànfaní láti kópa nínú ìbò náà.

Gbogbo àwọn oníṣẹ́ Wikimedia jákè-jádò agbáyé ni yóò kópa nínú ìdìbò yí ní inú ọdún 2021. Ó ṣe pàtàkì fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láti lè mú àlékún bá ṣíṣojú, ìkójọ pọ̀ ìmọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà.

Àwọn wo ni wọ́n lè díje sípò? Ṣe o ní ohun àmúyẹ láti díje sípò bí? O lè ṣe awárí siwájú si ní orí Dara pọ̀ mọ́ ìdíje

Ẹ ṣeun púpọ̀

Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe Àjọ Wikimedia