Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ Wikimedia Foundation/Àkópọ̀
Wikimedia Foundation
Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́
Njẹ́ o mọ̀ wípé nígbàtí ò nka ojú-ewé Wikipedia tí o fẹ́ràn jùlọ, àwọ́n ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni ó nṣiṣẹ́ láti rí dájú wípé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ yìí wà ní ọ̀fẹ́? |
Àwọn ará àjọṣepọ̀ ni ó wà káàkiri àgbáyé tí ó jẹ́ kí àwọn isẹ́-àkànṣe nlá bíi Wikipedia, Wikidata, Wikisource, etc. wà láàyè. |
Wikimedia Foundation ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà. Àjọ yìí ni ó nṣe ìtọ́jú fún àwọn ohun èlò ayélujára, àwọn ìpèníjà òfin ìjọba, àti àwọn ìṣòro. |
Wikimedia Foundation ní Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ tó bojútó àwọn iṣẹ́ àjọ yìí. À nyan àwọn onígbọ̀wọ́ yìí lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀ ní apákan, àti lát'ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ fún ra rẹ̀ ní apákejì. | |||
Àga 16 ni ó wà nínú Ìgbìmọ̀ yìí: |
|
Yíyàn fún àwọn àga lát'ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ má nwáyé nípa ètò ìwárii kárí-ayé. Wọn yí ò darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ nígbàtí ìgbìmọ̀ àwọn onígbọ̀wọ́ àti ẹni-ayàn náà bá ti gbà wípé iṣẹ́ náà yẹ fún wọn. |
Àwọn ará Wikipedia yí ò ní ànfààní láti dìbò fún onígbọ̀wọ́ lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará àjọṣepọ̀. Eléyì pèsè ànfààní láti lè mú àlékún bá ṣíṣojú, ìkójọ pọ̀ ìmọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà ní ìrísí ẹgbẹ́. |
Mọ̀ si nípa Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ àti bíí o ṣe lè kópa nínú ìdìbò ìgbìmọ̀ yìí lórí: https://w.wiki/yY9. |