Universal Code of Conduct/Enforcement draft guidelines review/Announcement/Short/yo

This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Enforcement draft guidelines review/Announcement/Short and the translation is 100% complete.

Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí - Àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́

Ìgbìmọ̀ fún Kíkọ ti Ipele Ìkejì Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí npè fún àwọn èrò lórí àwọn ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC). Àsìkò fún ìgbèròsílẹ̀ yìí ó wáyé láti 17 August 2021 títí dé 17 October 2021.

Àwọn Ìlànà kò parí síbí, ṣùgbọ́n o lè rànwá lọ́wọ́ láti gbe lọ síwájú. Ìgbìmọ̀ yìí ó ma ṣe àgbéyẹ̀wò rẹẹ̀ pẹ̀lú èrò lát'ọ̀dọ̀ àwọn ará Wikimedia.

O lè yan èdè tí ó bá wù ọ́ àti ọ̀nà tí o fẹ́ gbà kópa. A ó ṣètò àwọn ìjíròrò lórí ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia, ní oríṣiríṣi èdè. A nílò àwọn olùfarajìn láti báwa ṣètò àwọn ìjíròrò lórí àwọn iṣẹ́-àkànṣe ti wọn.

A ti ṣ'ètò àwọn ìjíròrò ayélujára lórí ìlànà ìgbófìnró àkọ́kọ́ UCoC yìí:

Ìpàdé Wikimania 2021 - 16 August @ 11:00 UTC - 11:45 UTC
Wákàtí ìjíròrò - 24 August, 31 August, 7 September @ 03:00 UTC & 14:00 UTC
Àwọn ìpè ìjíròrò - 18 September @ 03:00 UTC & 15:00 UTC

A ó gbè àwọn àkópọ̀ ìjíròrò jáde ní ojú-ewé yìí l'ọ̀sẹ́ méjì-méjì.

Ẹ jọ̀wọ́ kàn sí mi tí ẹ bá ní ìbéèrè kankan.