Wikimedia Foundation elections/2022/Announcement/Thirteen Candidates for the Board of Trustees

Outdated translations are marked like this.

Ìpè fún Àwọn Olùdíjè Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ ti 2022

O lè rí ìfiránṣẹ́ yìí ní àwọn èdè míràn lórí Meta-wiki.

Ìpè fún Àwọn Olùdíjè idibo Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ ti 2022 ti wá s'ópìn. Ìpè yìí yọrí sí ìforúkọsílẹ̀ àwọn olùdíje 12. Mọ̀ si nípa Àwọn Olùdíjè Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ ti 2022.

Ìgbìmọ̀ Alátúpalẹ̀ yí ò gbé àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀wẹ̀ àwọn olùdíje náà wò, ní ìlànà àwọn ohun-àmúyẹ tí àwọn onígbọ̀wọ́ ti là kalẹ̀. Ìgbìmọ̀ Àwọn Onígbọ̀wọ́ nwo àwọn ohun-àmúyẹ àti òye fún ìdàgbàsókè ìró agbára Ìgbìmọ̀ náà. Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ Alátúpalẹ̀ báti pári àtúnyẹ̀wò wọn, a ó ṣe àtẹ̀jáde ìgbéléwọ̀n olùdíje kọ̀ọ̀kan. Ìwọ̀n yìí wà fún ìdí ìfitónilétí nìkan ni.

Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìdìbò ìgbìmọ̀ àwọn onígbọ̀wọ́ 2022, o lè rí aago-iṣẹ́, àlàyé ìbò, àti àwọn ọ̀nà míràn tí o fi lè kópa lórí Meta-wiki.

Ẹ ṣeun fún àtìlẹ́yìn yin,

Movement Strategy àti Governance ní ìṣojú Ìgbìmọ̀ elétò Ìdìbò àti Ìgbìmọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́