Ọ̀rànmíyàn, tí a tún mọ̀ sí Ọranyan, jẹ́ Ọba Yorùbá kan láti Ìlú Ile-Ife, àti olùdásílẹ̀ ìjọba Ọ̀yọ́.[1] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbíkẹ́yìn nínú àwọn ìran Odùduwà, ó di olórí àrólé Odùduwà nígbà tí ó padà wá gba ìtẹ́ bàbá bàbá rẹ̀. [2]

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn Yorùbá ṣe sọ, ó dá Ọyọ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Aláàfín àkọ́kọ́ ní ọdún 1300 lẹ́yìn tí ó ti kúrò ní Benin níbi tí wọ́n ti fi jẹ ọba àkọ́kọ́ ti Benin.[3] Lẹ́yìn ikú Ọba Ọ̀rànmíyàn, ẹbí rẹ̀ ni wọ́n sọ pé wọ́n gbé òkúta ìrántí tí a mọ̀ sí Ọ̀pá Oranmiyan ní ibi tí bàbá àgbà wọn kú. Òpó òkúta yìí ga tó mítà márùn-ún ó lé márùn-ún, ó sì fi nǹkan bí mítà méjì ní gígùn ní ìsàlẹ̀.

Láàkókò ìjì líle kan ní ọdún 1884 bí mítà 1.2 ni ó yá kúrò ní òkè rẹ̀ àti pé ó ti ṣubú ní ìgbà méjì tí wọ́n sì tún gbé e sókè ní ìgbà kọ̀ọ̀kan. Lọ́wọ́lọ́wọ́ ó dúró ní igbó kan ní Mòpà, Ilé-Ifẹ̀. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa ohun tí wọ́n ń pè ní radiocarbon fi hàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà tí ìjọba Odùduwà bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti gbé òkúta ọba yìí kọ́.

Àwọn Ìtọ́kasí

edit
  1. "Journal of the Historical Society of Nigeria" 9 (3–4). Historical Society of Nigeria (University of California). 1978. 
  2. Ogumefu, M. I (1929). "The Staff of Oranyan". Yoruba Legends. Internet Sacred Text Archive. p. 46. Retrieved 2007-01-21. 
  3. G. T. Stride; Caroline Ifeka (1971). Peoples and empires of West Africa: West Africa in history, 1000-1800. Africana Pub. Corp (University of Michigan). p. 309. ISBN 9780841900691.