Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí/Ìwé Ìròyìn/4/Ìfiránṣẹ́ àgbáyé

This page is a translated version of the page Universal Code of Conduct/Newsletter/4/Global message and the translation is 100% complete.

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí - Abala Ìkẹ́rìn

Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí
Abala ìkẹ́rìn, Oṣù kẹ́jọ̀ọ 2021Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn


A kí yin káàbọ̀ sí abala ìkẹ́rìn Ìròyìn Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí! Ìwé ìròyìn yìí yio ran àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí ìlànà yìí, a ó sì tún pín àwọn ìròyìn, ìwádìí, àti àwọn àpèjọ tó jọmọ́ UCoC tó nbọ̀ lọ́nà.

Jọ̀wọ́ rántí láti fi orúkọ sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí a fi àwọn abala ìwé-ìròyìn tó nbọ̀ ránṣẹ́ sí yin, ẹ tún fi orúkọ yín sílẹ̀ níbí tí ẹ bá fẹ́ kí á ké sí yín fún ìtumọ̀ àwọn abala ìwé ìròyìn wa ní ọjọ́ iwájú.

  • Ìkánlẹ̀ Àgbéyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ inú Ìlànà Ìgbófìnró Àkọ́kọ́ - Àgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà Ìgbófìnró àkọ́kọ́ ti Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí yí ò wá sí òpin ní 17 October 2021, lẹ́yìn ìkànsí oṣù méjì. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Àwọn Wákàtí àti Ìpè Ìjíròrò - Àsìkò ìjókò míìràn láti jíròrò lórí EDGR wáyé ní àṣèyọrí ní 18 September 2021. Wákàtí ìjíròrò kan tí yí ò gbẹ̀yìn yí ò wáyé ní 15 October 2021.(ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ètò ìdìbò fún Ìgbìmọ̀ kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ - Ètò ìdìbò Ìgbìmọ̀ Kíkọ ti Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ ti bẹ̀rẹ̀, yí ò sì wá sí òpin ní 25 October 2021. Àwọn oníṣẹ́ iṣẹ́-àkànṣe Wikimedia lè dìbò fún àwọn olùdíje tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ ṣ'órí ìgbìmọ̀ náà. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Ìdarí Titun fún Ìwé-Ìròyìn yìí - Bí a ṣé nkágbá ètò ìkànsí fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí, ẹgbẹ́ olùṣètò ngbèrò ìdarí titun fún ìwé-ìròyìn yìí. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)
  • Búlọ́ọ̀gì Diff - Wo àwọn àtẹ̀jádè titun lórí ètò UCoC nínú Búlọ́ọ̀gì Diff ti Wikimedia. (ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́)